Ìfipamọ́ Noun Iṣẹ́ tí mo ṣe ń ṣe ìfipamọ́ sí inú àpò-àkápọ̀ àwòrán. The work I did is saving inside the picture folder Fi-pamọ́ Verb Fipamọ́ sí inú àpò-àkápọ̀ àwòrán. Save it in the picture folder. Ṣíra tẹ àtẹ̀ìpàṣẹ fipamọ́. Click on save button.
Ẹ̀rọ-ayí-ayéká Noun Ẹ̀rọ-ayí-ayéká (sátáláìtì) ni ẹ̀rọ-ojúọ̀run t'ó ń yí ayé ká tí ó sì ń mú ìtàkùrọ̀sọ r'ọrùn fún wa. Ní ọwọ́ tí a wà yìí, àwọn ẹ̀rọ-ayí-ayékátí ó ń yí bírí kárí ayé yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2218. Satellite is an object suspended in space that orbits the earth and it also make communication possible for us. Currently there are over 2218 satellites orbiting the Earth.
Àyíká iṣẹ́ Noun Àyíká iṣẹ́ ni àyíká tí ètò ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ pèsè fún iṣẹ́ àìrídìmú kan láti ṣe iṣẹ́ tàbí pa itú ọwọ́ rẹ̀. A runtime environment is the execution environment provided to an application or software by the operating system.