3
Jun
Off
Ìfimọ́ Ì + fi + mọ́  Fi ìfimọ́ kún un kí o tó fi ránṣẹ́. Add an attachment to it before you send. Mo fi àwòrán ìwé-ẹ̀rí ìmọ̀-ẹ̀rọ mọ́ iṣẹ́-ìjẹ́ tí mo fi ṣọwọ́ sí iléeṣẹ́ abániwáṣẹ́. I attached a technology proficiency certificate to the message that I sent to the employment office.
3
Jun
Off
Iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ Noun Iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ  Iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ, tàbí ohun èlò orí ẹ̀rọ ni àwọn iṣẹ́ àìrídìmú tí ó wà lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá rẹ. Aṣàwáríkiri orí ayélujára, iṣẹ́ orí ẹ̀rọ fún ìkọ̀wé ránṣẹ́, ohun èlò ìtẹ-ọ̀rọ̀, ohun ìṣeré, àti àwọn ohun èlò gbogbo ní orí ẹ̀rọ ni iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ. An application, or application program, is a software program that runs on your computer. Web browsers, e-mail programs, word processors, games, and...
8
May
Off
Òye tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) Òye tí kì í ṣe ti ẹ̀dá [ọmọ ènìyàn] Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀rọ ayárabíàṣá tí ó ń ṣe ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀rọ oní-òye, tí ó ń ronú àti ṣiṣẹ́ bí ẹ̀dá ọmọ-ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ ìdáfọ̀mọ̀, wíwà ojútùú síṣòro, tòun ti kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti ìṣètò nǹkan. Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá náà ló ṣe atọ́nà Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́. Artificial Intelligence (AI) is the branch of...
27
Mar
Off
Fifún Verb Fi + fún (give out) Nígbà tí Ọpẹ́yẹmí kọ orúkọ sílẹ̀ tán, ó ṣíra tẹ fifun. After Ọpẹ́yẹmí has entered her name/subscribed, she clicked on submit. Fi ìbéèrè fún Google. Submit a query to Google.
27
Mar
Off
Ipò Noun Èyí ni atọ́ka sí ipò tí ẹ̀rọ tàbí ònṣàmúlò wà, fún àpẹẹrẹ; ipò ìjáde; ipò àìṣedéédé ẹ̀rọ... This is a pointer to the state (condition) of a device or user, for example; exit status, device malfunctioning status...  
27
Mar
Off
Ìráàyèwẹ̀rọfiṣẹ́ẹ̀jẹ́ránṣẹ́ Verb Ìrí-àyè-wọ-ẹ̀rọ-fi-iṣẹ́-ìjẹ́-ránṣẹ́ Èdè ìperí ìráàyèwẹ̀rọfiṣẹ́ẹ̀jẹ́ránṣẹ́ ni dídíbọ́n tàbí títakóró wọ inú ẹ̀rọ, inú iṣẹ́ àìrídìmú, awo àrídìmú tàbí ẹ̀rọ ayárabíàṣá ẹlòmìíràn.  The term spoof refers to hacking or deception that imitates another person, software program, hardware device, or computer.   
22
Mar
Off
Ìránsíwájú Ímeèlì Noun Ìránsíwájú Ímeèlì ni iṣẹ́ fífi iṣẹ́-ìjẹ́ tí a gbà sínú ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára kan ránṣẹ́ sí ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára ẹlòmíràn tàbí àwọn ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára mìíràn síwájú sí i.  Email forwarding refers to the operation of re-sending an email message delivered to one email address to one or more different email addresses.
22
Mar
Off
Òǹṣàmúlò Noun Òǹṣàmúlò ni ẹni tí ó ń ṣe àmúlò ẹ̀rọ ayárabíàṣá tàbí iṣẹ́ orí ìsopọ̀. Òǹṣàmúlò sábà máa ń ní ìṣàmúlò tí ẹ̀rọ máa ń dá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí i orúkọ-òǹṣàmúlò (tàbí orúkọ òǹṣàmúlò). A user is a person who utilizes a computer or network service. A user often has a user account and is identified to the system by a username (or user name). Other terms for username include login name, screenname (or screen name), account name, nickname (or nick) and handle, 
22
Mar
Off
Òṣùwọ̀n ìgbóná Noun Òṣùwọ̀n-ìgbóná ni ohun èlò tí a fi ń yẹ ìwọ̀n òtútù àti ìgbóná nǹkan wò láti mọ bí nǹkan náà ṣe tutù tàbí gbóná sí. A thermometer is an instrument for measuring or showing temperature (how hot or cold something is).