3
Jun
Off
Ìkójọpamọ́ Noun Ì + kó + jọ + pa + mọ́  Ìkójọpamọ́ ni ẹ̀dá iṣẹ́ tí a mú fi pamọ́ sí ìbòmíràn tí ó ṣe é gbà padà bí a bá pàdánù rẹ. Backup is a copy of work taken and stored elsewhere so that it may be used to restore the original after a data loss event. Verb Kó + jọ + pa + mọ́
3
Jun
Off
Ìdádúró Noun Ì + dá + dúró (delay) Àpọ̀jù òǹlò lórí ẹ̀rọ ìtàkùrọ̀sọ ní máa ń fa ìdádúró Communications system saturation  results in backlog. 
27
Mar
Off
Ipò Noun Èyí ni atọ́ka sí ipò tí ẹ̀rọ tàbí ònṣàmúlò wà, fún àpẹẹrẹ; ipò ìjáde; ipò àìṣedéédé ẹ̀rọ... This is a pointer to the state (condition) of a device or user, for example; exit status, device malfunctioning status...  
27
Mar
Off
Ìráàyèwẹ̀rọfiṣẹ́ẹ̀jẹ́ránṣẹ́ Verb Ìrí-àyè-wọ-ẹ̀rọ-fi-iṣẹ́-ìjẹ́-ránṣẹ́ Èdè ìperí ìráàyèwẹ̀rọfiṣẹ́ẹ̀jẹ́ránṣẹ́ ni dídíbọ́n tàbí títakóró wọ inú ẹ̀rọ, inú iṣẹ́ àìrídìmú, awo àrídìmú tàbí ẹ̀rọ ayárabíàṣá ẹlòmìíràn.  The term spoof refers to hacking or deception that imitates another person, software program, hardware device, or computer.   
22
Mar
Off
Ìránsíwájú Ímeèlì Noun Ìránsíwájú Ímeèlì ni iṣẹ́ fífi iṣẹ́-ìjẹ́ tí a gbà sínú ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára kan ránṣẹ́ sí ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára ẹlòmíràn tàbí àwọn ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára mìíràn síwájú sí i.  Email forwarding refers to the operation of re-sending an email message delivered to one email address to one or more different email addresses.
22
Mar
Off
Okùn Noun Nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, okùn ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ààmì/ọ̀rọ̀ t’ó ń ṣiṣẹ́ kan. In computer programming, a string is a sequence of characters for a certain purpose.
22
Mar
Off
Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká Noun Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká ni ohun èlò tí a fi ń wọn ọ̀rìnrìn àyíká, tí a fi ń ṣe ìwòye ojú-ọjọ́ àti gíga. Baros tí ó túmọ̀ sí “ìwúwo” + meter "ìwọ̀n/òṣùwọ̀n" = Ẹ̀rọ òṣùwọ̀n èéfún afẹ́fẹ́ ojú-ọjọ́. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ Robert Boyle ló hu ìmọ̀ èdè-ìperí náà (1627-1691). Ọdún 1643 ni ọmọ ilẹ̀ Italy Evangelista Torricelli tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀dá-àrígbéwọ̀n hùmọ̀ ohun-èlò náà tí wọ́n kọ́kọ́...
22
Mar
Off
Òṣùwọ̀n-iná-mànàmáná Noun Òṣùwọ̀n-iná-mànàmáná ni irúfẹ́ ẹ̀rọ kan t’ó ń wọn iye iná tí ilé, iléeṣẹ́, tàbí ẹ̀rọ aloná ń lò. An electricity meter or energy meter is a device that measures the amount of electric energy consumed by a residence, business, or an electrically powered device.  
22
Mar
Off
Iṣẹ́-àìrídìmú Noun Fi iṣẹ́-àìrídìmú fún àwòrán yíyà sí orí ẹ̀rọ. Install graphic design Software on the system.