Kòkòrò aṣàṣìṣe Noun Ní ọjọ́ 9 oṣù Ọ̀wẹwẹ̀, 1947 Grace rí àṣìṣe kan ní orí ẹ̀rọ Mark II tí àfòpiná kan tí ó kú sínú rẹ̀ fà. Ó yọ kòkòrò náà ó sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ìwé àkọsílẹ̀, báyìí ni a ṣe hu èdè ìperí kòkòrò aṣàṣìṣe orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá. Láti ìgbà náà lọ ni "kòkòrò aṣàṣìṣe" di èdè ìperí fún ìṣàpèjúwe àṣìṣe tàbí àléébù...
Ìkójọpamọ́ Noun Ì + kó + jọ + pa + mọ́ Ìkójọpamọ́ ni ẹ̀dá iṣẹ́ tí a mú fi pamọ́ sí ìbòmíràn tí ó ṣe é gbà padà bí a bá pàdánù rẹ. Backup is a copy of work taken and stored elsewhere so that it may be used to restore the original after a data loss event. Verb Kó + jọ + pa + mọ́
Ìfimọ́ Ì + fi + mọ́ Fi ìfimọ́ kún un kí o tó fi ránṣẹ́. Add an attachment to it before you send. Mo fi àwòrán ìwé-ẹ̀rí ìmọ̀-ẹ̀rọ mọ́ iṣẹ́-ìjẹ́ tí mo fi ṣọwọ́ sí iléeṣẹ́ abániwáṣẹ́. I attached a technology proficiency certificate to the message that I sent to the employment office.
Iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ Noun Iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ Iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ, tàbí ohun èlò orí ẹ̀rọ ni àwọn iṣẹ́ àìrídìmú tí ó wà lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá rẹ. Aṣàwáríkiri orí ayélujára, iṣẹ́ orí ẹ̀rọ fún ìkọ̀wé ránṣẹ́, ohun èlò ìtẹ-ọ̀rọ̀, ohun ìṣeré, àti àwọn ohun èlò gbogbo ní orí ẹ̀rọ ni iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ. An application, or application program, is a software program that runs on your computer. Web browsers, e-mail programs, word processors, games, and...
Òye tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) Òye tí kì í ṣe ti ẹ̀dá [ọmọ ènìyàn] Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀rọ ayárabíàṣá tí ó ń ṣe ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀rọ oní-òye, tí ó ń ronú àti ṣiṣẹ́ bí ẹ̀dá ọmọ-ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ ìdáfọ̀mọ̀, wíwà ojútùú síṣòro, tòun ti kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti ìṣètò nǹkan. Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá náà ló ṣe atọ́nà Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́. Artificial Intelligence (AI) is the branch of...
Ìṣàn Tààrà (DC) Ìṣàn tààrà (DC) ni irúfẹ́ ìṣàn iná mànàmáná tí ó máa ń ṣàn tààrà sí ìhà kan ṣoṣo. DC ní igun méjì tí ó dúró fún + àti -, fún àpẹẹrẹ àwọn òkúta agbagbára-iná-sára gbogbo ni ó jẹ́ ìṣàn tààrà. Kí á má fi ikú wé oorun, agbára iná DC kì í ṣe ẹgbẹ́ra pẹ̀lú ti AC. Direct current (DC) is an...