17
Mar
Off
Ẹnu-àbáwọlé ṣiṣẹ́ Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Orí ibùdó-ìtakùn ẹnu-àbáwọlé ṣiṣẹ́ ilé ìwé wọn ni mo ti rí i. It is on their school web portal that I (saw) found it.
16
Mar
Off
Oríta ìbáṣepọ̀ òǹṣàmúlò Oríta tí àwọn nǹkan tàbí ọmọ ènìyàn àti nǹkan (bí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá) ti máa ń pàdé ni interface. Torí ìdí èyí, oríta ìbáṣepọ̀ òǹṣàmúlò (ìyẹn UI ní Gẹ̀ẹ́sì) ni àyè tí ìbáṣepọ̀ láàárín ẹ̀dá ọmọ ènìyàn àti ẹ̀rọ ti máa ń wáyé. The point or place where things or human and things (like computer) meet is the interface. Therefore, a user interface (UI) is...
16
Mar
Off
Àjúmọ̀ṣe Ìkànnì ìkéde Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé (Adjective)  Àjúmọ̀ṣe Ìkànnì ìkéde ni àwọn ohunèlò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá tí ó máa ń f'èsì sí ohunkóhun tí ònṣàmúlò bá ṣe nípasẹ̀ ìgbéjáde àwọn àkóónú ọ̀rọ̀, àwòrán tí ó ń ṣípò, àwòrándààyè, àwòrán-olóhùn, ohùn, àti àwọn ohun ìṣeré oláwòrán-olóhùn. Interactive media refers to products and services on digital computer-based systems which respond to the user's actions by presenting content such as...
16
Mar
Off
Àtẹìjúwe Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun)  Àtẹìjúwe Fi ìwífún-alálàyé tí o gbà jọ ṣe ìpìlẹ̀ àtẹìjúwe. Use the data that you collated to develop a graph.
16
Mar
Off
Ìkànnì ìkéde Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìkànnì ìkéde jẹ́ àwọn ìlànà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tàbí ìkéde. Bákan náà ni a lè lo èdè ìperí náà fún àwọn fún ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn / atẹ̀ròyìn. Bí àpẹẹrẹ, ìkànnì ìkéde ni ìwé ìròyìn, ẹ̀rọ-amóhùnmáwòràn, ẹ̀rọ-asọ̀rọ̀mágbèsì, ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Media refers to the different means of communication. Also we can use the term for news agencies / press. For example, media...
21
Jan
Off
Pátákó-ìdìmú Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Pátákó-ìdìmú   Pátákó kékeré tí ó ní iga ìdìmú lórí, tí ó ṣe é mú ìwé (tákàdá) dání tí ó sì ń ṣe àtìlẹ́yìn fún ìkọ̀wé A small board with a spring clip at the top, used for holding papers and providing support for writing.   Ìtumọ̀ Mìíràn Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Pátákó-ìdìmú Nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ̀ ayárabíàṣà, pátákó-ìdìmú ni ìbi ìpamọ̀ ìgbà díẹ̀ tí...
21
Jan
Off
Daríkiri Ọ̀rọ̀-Ìṣe (Verb) Da+orí+kiri [Daríkiri] Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gboyè daríkiri/lọ kiri ètò náà bí wọ́n ṣe ń tẹ iṣẹ́ ìwádìí wọn jáde Graduate students navigate the system as they publish research.   Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìda+orí+kiri [Ìdaríkiri] Ìdaríkiri ọkọ̀ lójú pópó Navigation of vehicle on the highway.   Ìtumọ̀ Mìíràn Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìtu+ọkọ̀ [Ìtukọ̀] Ìtukọ̀ ojú omi Water (river, ocean, sea) navigation.   Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Atu+ọkọ̀ [Atukọ̀]...
8
May
Off
Òye tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) Òye tí kì í ṣe ti ẹ̀dá [ọmọ ènìyàn] Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀rọ ayárabíàṣá tí ó ń ṣe ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀rọ oní-òye, tí ó ń ronú àti ṣiṣẹ́ bí ẹ̀dá ọmọ-ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ ìdáfọ̀mọ̀, wíwà ojútùú síṣòro, tòun ti kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti ìṣètò nǹkan. Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá náà ló ṣe atọ́nà Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́. Artificial Intelligence (AI) is the branch of...