Fifún Verb Fi + fún (give out) Nígbà tí Ọpẹ́yẹmí kọ orúkọ sílẹ̀ tán, ó ṣíra tẹ fifun. After Ọpẹ́yẹmí has entered her name/subscribed, she clicked on submit. Fi ìbéèrè fún Google. Submit a query to Google.
Ipò Noun Èyí ni atọ́ka sí ipò tí ẹ̀rọ tàbí ònṣàmúlò wà, fún àpẹẹrẹ; ipò ìjáde; ipò àìṣedéédé ẹ̀rọ... This is a pointer to the state (condition) of a device or user, for example; exit status, device malfunctioning status...
Ìráàyèwẹ̀rọfiṣẹ́ẹ̀jẹ́ránṣẹ́ Verb Ìrí-àyè-wọ-ẹ̀rọ-fi-iṣẹ́-ìjẹ́-ránṣẹ́ Èdè ìperí ìráàyèwẹ̀rọfiṣẹ́ẹ̀jẹ́ránṣẹ́ ni dídíbọ́n tàbí títakóró wọ inú ẹ̀rọ, inú iṣẹ́ àìrídìmú, awo àrídìmú tàbí ẹ̀rọ ayárabíàṣá ẹlòmìíràn. The term spoof refers to hacking or deception that imitates another person, software program, hardware device, or computer.
Òǹṣàmúlò Noun Òǹṣàmúlò ni ẹni tí ó ń ṣe àmúlò ẹ̀rọ ayárabíàṣá tàbí iṣẹ́ orí ìsopọ̀. Òǹṣàmúlò sábà máa ń ní ìṣàmúlò tí ẹ̀rọ máa ń dá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí i orúkọ-òǹṣàmúlò (tàbí orúkọ òǹṣàmúlò). A user is a person who utilizes a computer or network service. A user often has a user account and is identified to the system by a username (or user name). Other terms for username include login name, screenname (or screen name), account name, nickname (or nick) and handle,
Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká Noun Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká ni ohun èlò tí a fi ń wọn ọ̀rìnrìn àyíká, tí a fi ń ṣe ìwòye ojú-ọjọ́ àti gíga. Baros tí ó túmọ̀ sí “ìwúwo” + meter "ìwọ̀n/òṣùwọ̀n" = Ẹ̀rọ òṣùwọ̀n èéfún afẹ́fẹ́ ojú-ọjọ́. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ Robert Boyle ló hu ìmọ̀ èdè-ìperí náà (1627-1691). Ọdún 1643 ni ọmọ ilẹ̀ Italy Evangelista Torricelli tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀dá-àrígbéwọ̀n hùmọ̀ ohun-èlò náà tí wọ́n kọ́kọ́...
Òṣùwọ̀n-iná-mànàmáná Noun Òṣùwọ̀n-iná-mànàmáná ni irúfẹ́ ẹ̀rọ kan t’ó ń wọn iye iná tí ilé, iléeṣẹ́, tàbí ẹ̀rọ aloná ń lò. An electricity meter or energy meter is a device that measures the amount of electric energy consumed by a residence, business, or an electrically powered device.
Ibi-òǹṣàmúlò Noun Ibi òǹṣàmúlò ni aṣojú tí í ṣe ìdánimọ̀ ẹni lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá. Mú ibi-òǹṣàmúlò Twitter rẹ ṣiṣẹ́ padà. A profile refers to the explicit digital representation of a person's identity. Reactivate your Twitter profile.
Ìdáfọ̀mọ̀ Noun Ìdá-ìfọ̀-mọ̀ Àbùdá Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ l'ó bí Ìdá-ìfọ̀-mọ̀, Ọ̀rọ̀-di-ohùn àti Ohùn-di-ọ̀rọ̀-kíkọ-sílẹ̀. Machine learning feature gave birth to Speech Recognition, Text-to-Speech and Speech-to-text.