8
Sep
Off
Ètò ìṣiṣẹ́-ẹ̀rọ Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun)    Ètò ìṣiṣẹ́-ẹ̀rọ ni ètò iṣẹ́-àìrídìmú tí í ṣe àkóso iṣẹ́-àìrídìmú ẹ̀rọ ayárabíàṣá, ohun-àmúlò iṣẹ́-àìrídìmú, tí ó sì ń bá àwọn onírúurú iṣẹ́ orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá ṣiṣẹ́. ... Ètò ìṣiṣẹ́-ẹ̀rọ máa ń wà ní orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn awo tí ó ní ẹ̀rọ ayárabíàṣá nínú – láti orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alòkúta-agbára-iná àti àwọn àpótí ẹ̀rọ ìṣiré títí kan àwọn apèsè ibùdó ìtakùn...
15
Sep
Off
Ìfèròkójọ Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìfi + èrò + kó + jọ Ìfèròkójọ jẹ́ àkójọ ìwífún, èròńgbà, tàbí iṣẹ́ láti ọwọ́ àwọn ènìyàn, tí ó jẹ́ wípé orí ẹ̀rọ ayélujára ni a ti kó o jọ. Iṣẹ́ ìfèròkójọ fi àyè gba àwọn ilé-iṣẹ́ láti dín àkókò àti owó kù bí wọ́n ṣe ń bù mu nínú omi ìmọ̀óṣe tàbí èrò ọkàn onírúurú àwọn ènìyàn jákèjádò ilé-ayé. Crowdsourcing...
15
Sep
Off
Ìwífún-alálàyé Ìṣísílẹ̀ gbangba Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìwífún-alálàyé Ìṣísílẹ̀ gbangba  Ìwífún-alálàyé ìṣísílẹ̀ gbangba ni awon ìwífún-alálàyé tí ẹnikẹ́ni lè rí ààyè sí, mú lò àti pín fún elòmíràn láti tún lò. Ìjọba, okoòwò àti àwọn ènìyàn lè ṣe àmúlò àwọn ìwífún-alálàyé tí ó ṣí sílẹ̀ gbangba fún ìmúwá ànfààní fún àwùjọ, ọro-ajé àti àyíká. Open data is data that anyone can access, use and share. Governments, businesses and...
15
Sep
Off
Iṣẹ́-àìrídìmú Olórísun Ìṣísílẹ̀-Gbangba Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Iṣẹ́-àìrídìmú Olórísun Ìṣísílẹ̀-Gbangbà Iṣẹ́-àìrídìmú Olórísun Ìṣísílẹ̀-Gbangba ni àkọ́kọ́ irú àjùmòlò tí a tọ́ka sí t'ó so èso rere gẹ́gẹ́ bí i ìgbésẹ̀ àjùmọ̀ṣe tí ó ti sún síwájú rékọjá ìmọ̀-ẹ̀rọ lo. Open source software is cited as the first domain where networked open sharing produced a tangible benefit as a movement that went much further than technology.   Using equipment...
15
Sep
Off
Ìráàyèsí Ìṣísílẹ̀ Gbagba wálíà Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun)̀ Ara wọn ni ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọ-ènìyàn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí àtúnpadàṣe àṣẹ-ẹ̀dá jákèjádò ilé-ayé, awon aṣòfin àkóso ìlú tí ó ń jà fún ìráàyèsí ìṣísílẹ̀-gbangba wálíà àwọn ohun ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi owó ìlú ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀, ìṣe-ìwádìí àti ìwífún-alálàyé, àti àwọn oníṣẹ́-ọpọlọ tí ó mọ rírì pínpín iṣẹ́ fún ìlò gbogboògbò. This includes activists working on copyright reform around...
15
Sep
Off
Aṣiṣẹ́fúnrarẹ̀ Ẹ̀yán-ọ̀rọ̀ (Adjective) A + ṣiṣẹ́ + fún + ara + rẹ̀ (Ohun tí ó ń ṣiṣẹ́ fúnra rẹ̀) Ìbọn tí ó ń ṣiṣẹ́ (yin ọta) fúnra rẹ̀ ni àwọn ọlọ́ṣà náà gbé wá jalè. It is an automatic gun that the robbers brought for the robbery (the robbers brought automatic guns to rob).
15
Sep
Off
Ìdàṣiṣẹ́fúnrarẹ̀ Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìdà + ṣiṣẹ́ + fún + ara + rẹ̀  Àdá + ṣiṣẹ́ + fún + ara + rẹ̀ Lílò irinṣẹ́ tàbí àwọn ẹ̀rọ tí ó ń dá ṣiṣẹ́ (fún ara rẹ̀) láì nílò ìkúnpá ẹ̀dá ọmọ ènìyàn.   Using equipment or machines that operates (automatic) on its own.
14
Sep
Off
Asàwòrándààyè Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Asọ + àwòrán + di + ààyè A nílò asàwòrándààyè fún iṣẹ́ àkànṣe kan. We need an animator for a project. .
14
Sep
Off
Sàwòrándààyè Ọ̀rọ̀-ìse (Verb) Sọ + àwòrán + di + ààyè Babájídé sọ àwòrán igi ọ̀pẹ dààyè.Babájídé animated a palm-tree.   Wo animation.
14
Sep
Off
Ìṣàwòrándààyè Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìṣọ + àwòrán + di + ààyè Mo wo ìran ìsàwòrándààyè Ṣàngó kan lórí YouTube. I saw/watched a Ṣàngó animation on YouTube.