27
Mar
Off
Fifún Verb Fi + fún (give out) Nígbà tí Ọpẹ́yẹmí kọ orúkọ sílẹ̀ tán, ó ṣíra tẹ fifun. After Ọpẹ́yẹmí has entered her name/subscribed, she clicked on submit. Fi ìbéèrè fún Google. Submit a query to Google.
22
Mar
Off
Ìránsíwájú Ímeèlì Noun Ìránsíwájú Ímeèlì ni iṣẹ́ fífi iṣẹ́-ìjẹ́ tí a gbà sínú ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára kan ránṣẹ́ sí ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára ẹlòmíràn tàbí àwọn ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára mìíràn síwájú sí i.  Email forwarding refers to the operation of re-sending an email message delivered to one email address to one or more different email addresses.
22
Mar
Off
Òǹṣàmúlò Noun Òǹṣàmúlò ni ẹni tí ó ń ṣe àmúlò ẹ̀rọ ayárabíàṣá tàbí iṣẹ́ orí ìsopọ̀. Òǹṣàmúlò sábà máa ń ní ìṣàmúlò tí ẹ̀rọ máa ń dá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí i orúkọ-òǹṣàmúlò (tàbí orúkọ òǹṣàmúlò). A user is a person who utilizes a computer or network service. A user often has a user account and is identified to the system by a username (or user name). Other terms for username include login name, screenname (or screen name), account name, nickname (or nick) and handle, 
22
Mar
Off
Òṣùwọ̀n ìgbóná Noun Òṣùwọ̀n-ìgbóná ni ohun èlò tí a fi ń yẹ ìwọ̀n òtútù àti ìgbóná nǹkan wò láti mọ bí nǹkan náà ṣe tutù tàbí gbóná sí. A thermometer is an instrument for measuring or showing temperature (how hot or cold something is). 
22
Mar
Off
Okùn Noun Nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, okùn ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ààmì/ọ̀rọ̀ t’ó ń ṣiṣẹ́ kan. In computer programming, a string is a sequence of characters for a certain purpose.
22
Mar
Off
Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká Noun Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká ni ohun èlò tí a fi ń wọn ọ̀rìnrìn àyíká, tí a fi ń ṣe ìwòye ojú-ọjọ́ àti gíga. Baros tí ó túmọ̀ sí “ìwúwo” + meter "ìwọ̀n/òṣùwọ̀n" = Ẹ̀rọ òṣùwọ̀n èéfún afẹ́fẹ́ ojú-ọjọ́. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ Robert Boyle ló hu ìmọ̀ èdè-ìperí náà (1627-1691). Ọdún 1643 ni ọmọ ilẹ̀ Italy Evangelista Torricelli tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀dá-àrígbéwọ̀n hùmọ̀ ohun-èlò náà tí wọ́n kọ́kọ́...
22
Mar
Off
Iṣẹ́-àrídìmú Noun Pàrọ̀ Iṣẹ́-àrídìmú ẹ̀rọ-ayàwòrán. Change the camera Hardware.
22
Mar
Off
Iṣẹ́-àìrídìmú Noun Fi iṣẹ́-àìrídìmú fún àwòrán yíyà sí orí ẹ̀rọ. Install graphic design Software on the system.