Ibi-òǹṣàmúlò Noun Ibi òǹṣàmúlò ni aṣojú tí í ṣe ìdánimọ̀ ẹni lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá. Mú ibi-òǹṣàmúlò Twitter rẹ ṣiṣẹ́ padà. A profile refers to the explicit digital representation of a person's identity. Reactivate your Twitter profile.
Àfọ́ di kíkọ sílẹ̀ Noun Bí kò sí Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́, kò sí àfọ́-di-kíkọ-sílẹ̀. Àpèkọ ni ìmọ̀ ọgbọ́n-àmúṣe arannilọ́wọ́ fún ẹni tí kíkọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ ṣòro fún. Àpèkọ náà ni à ń pè ní "àfọ́ di kíkọ-sílẹ̀," "ohùn di ọ̀rọ̀ kíkọ sílẹ̀" tàbí "ìdáfọ̀mọ̀". If there is no Machine Learning, there is no Speech-to-Text. Dictation is an assistive technology tool that can help with writing issues. Dictation...
Ọ̀rọ̀ọ́-di-ohùn Noun Ọ̀rọ̀ọ́-di-ohùn ni yó ka ohun t'ó wà lójú-ẹ̀rọ l’óhùn. Ọ̀rọ̀ọ́ di ohùn ni ọgbọ́n-àmúṣe àfọ̀ tí ó ń yí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ di ohùn. Nítorí àwọn tí kò ríran ni a fi pèsè ohùn àfọ̀ ti ẹ̀rọ tí yó "ka" ọ̀rọ̀ sẹ́tígbọ̀ọ́ òǹṣàmúlò. It is Text-to-speech that reads what is on the screen using voice. Text to speech (TTS), is...
Ìdáfọ̀mọ̀ Noun Ìdá-ìfọ̀-mọ̀ Àbùdá Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ l'ó bí Ìdá-ìfọ̀-mọ̀, Ọ̀rọ̀-di-ohùn àti Ohùn-di-ọ̀rọ̀-kíkọ-sílẹ̀. Machine learning feature gave birth to Speech Recognition, Text-to-Speech and Speech-to-text.
Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ Noun Kíkọ́ ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ l'ó mú kí ìṣèṣàtúnkọ-ẹ̀rọ àti àsọtẹ́lẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀rọ̀ ó ṣe é ṣe. Kíkọ́ ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ètò òye tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) tí ó ń fi àyè gba ẹ̀rọ láti kọ́ ẹ̀kọ́ kún ẹ̀kọ́ fún ara rẹ̀ látàrí ìrírí láì ṣe wí pé allows ènìyàn fi ìmọ̀ bọ́ ọ. Pẹ̀lú àbùdá Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ àwọn iṣẹ́ àìrídìmú leè ṣá ọ̀rọ̀ ìwífún alálàyé jọ fún...
Ẹ̀rọ-ìdíwọ̀n ìgbóná àti ìtútù Noun Ẹ̀rọ tí ó máa ń fi ìdiwọ̀n ìgbóná àti òtútù Ẹ̀rọ tí ó máa ń ṣe ìwọ̀ntúnwọ̀nsì sí ìgbóná tàbí ìtutù, ó sì tún máa ń mú ẹ̀rọ ṣiṣẹ́ bí ìgbóná/ìtutù bá dé ìwọ̀n kan. A device that automatically regulates temperature, or that activates a device when the temperature reaches a certain point.