Ìfimọ́ Ì + fi + mọ́ Fi ìfimọ́ kún un kí o tó fi ránṣẹ́. Add an attachment to it before you send. Mo fi àwòrán ìwé-ẹ̀rí ìmọ̀-ẹ̀rọ mọ́ iṣẹ́-ìjẹ́ tí mo fi ṣọwọ́ sí iléeṣẹ́ abániwáṣẹ́. I attached a technology proficiency certificate to the message that I sent to the employment office.
Iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ Noun Iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ Iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ, tàbí ohun èlò orí ẹ̀rọ ni àwọn iṣẹ́ àìrídìmú tí ó wà lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá rẹ. Aṣàwáríkiri orí ayélujára, iṣẹ́ orí ẹ̀rọ fún ìkọ̀wé ránṣẹ́, ohun èlò ìtẹ-ọ̀rọ̀, ohun ìṣeré, àti àwọn ohun èlò gbogbo ní orí ẹ̀rọ ni iṣẹ́-orí-ẹ̀rọ. An application, or application program, is a software program that runs on your computer. Web browsers, e-mail programs, word processors, games, and...
Òye tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) Òye tí kì í ṣe ti ẹ̀dá [ọmọ ènìyàn] Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀rọ ayárabíàṣá tí ó ń ṣe ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀rọ oní-òye, tí ó ń ronú àti ṣiṣẹ́ bí ẹ̀dá ọmọ-ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ ìdáfọ̀mọ̀, wíwà ojútùú síṣòro, tòun ti kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti ìṣètò nǹkan. Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá náà ló ṣe atọ́nà Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́. Artificial Intelligence (AI) is the branch of...
Ìṣàn Tààrà (DC) Ìṣàn tààrà (DC) ni irúfẹ́ ìṣàn iná mànàmáná tí ó máa ń ṣàn tààrà sí ìhà kan ṣoṣo. DC ní igun méjì tí ó dúró fún + àti -, fún àpẹẹrẹ àwọn òkúta agbagbára-iná-sára gbogbo ni ó jẹ́ ìṣàn tààrà. Kí á má fi ikú wé oorun, agbára iná DC kì í ṣe ẹgbẹ́ra pẹ̀lú ti AC. Direct current (DC) is an...
Sanwósí Verb San + owó + sí Sanwósí orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká rẹ. Subscribe on your mobile phone. Fi + ọwọ́ + sí Fọwọ́sí ìgbàròyìn tuntun Subscribe to get the latest news
Owóòlò-ayélujára orí ẹ̀rọ-alágbèéká Noun Owó + ìlò + ayélujára orí ẹ̀rọ-alágbèéká Owóòlò-ayélujára orí ẹ̀rọ-alágbèéká ni àwọn àkópọ̀ ohun orí ayélujára tí a gbé sórí ẹ̀rọ bí i ẹ̀rọ-alágbèéká àti ẹ̀rọ-ọlọ́pọ́n tí ó la orí ìsopọ̀ àìlokùn ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́. Mobile data is Internet content delivered to mobile devices such as smartphones and tablets over a wireless cellular connection.
Ìsanwósí Noun Ìsan + owó + sí (to pay to have access to something) Mo ṣe ìsanwósí DSTV. I did a DSTV subscription. Ìfi + orúkọ + sílẹ̀ (to put down one's name/register for a purpose; for access to something) Jẹ́ kí a lọ ṣe ìforúkọsílẹ̀ fún owó-ìlò-ayélujára Let us go for subscription for internet data.
Fifún Verb Fi + fún (give out) Nígbà tí Ọpẹ́yẹmí kọ orúkọ sílẹ̀ tán, ó ṣíra tẹ fifun. After Ọpẹ́yẹmí has entered her name/subscribed, she clicked on submit. Fi ìbéèrè fún Google. Submit a query to Google.
Ipò Noun Èyí ni atọ́ka sí ipò tí ẹ̀rọ tàbí ònṣàmúlò wà, fún àpẹẹrẹ; ipò ìjáde; ipò àìṣedéédé ẹ̀rọ... This is a pointer to the state (condition) of a device or user, for example; exit status, device malfunctioning status...