16
Mar
Off
Ìkànnì ìkéde Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìkànnì ìkéde jẹ́ àwọn ìlànà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tàbí ìkéde. Bákan náà ni a lè lo èdè ìperí náà fún àwọn fún ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn / atẹ̀ròyìn. Bí àpẹẹrẹ, ìkànnì ìkéde ni ìwé ìròyìn, ẹ̀rọ-amóhùnmáwòràn, ẹ̀rọ-asọ̀rọ̀mágbèsì, ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Media refers to the different means of communication. Also we can use the term for news agencies / press. For example, media...
16
Mar
Off
Ìfihàn ní gbangba Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun)  Ìfihàn ní gbangba Iléeṣẹ́ náà ṣe ìfihàn-ní-gbangba láti polówó ọjà rẹ̀ tuntun The company did a demonstration to promote her new product Ẹgbẹ́ akọrin tàkàsúfèé àṣẹ̀ṣẹ̀ dá ń ṣe ìfihàn ní gbangba fún ìgbáradì ìkáhùnsílẹ̀ àwo orin wọn The newly formed hip-hop group is doing a demo in preparation for the recording of its music album
21
Jan
Off
Pátákó-ìdìmú Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Pátákó-ìdìmú   Pátákó kékeré tí ó ní iga ìdìmú lórí, tí ó ṣe é mú ìwé (tákàdá) dání tí ó sì ń ṣe àtìlẹ́yìn fún ìkọ̀wé A small board with a spring clip at the top, used for holding papers and providing support for writing.   Ìtumọ̀ Mìíràn Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Pátákó-ìdìmú Nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ̀ ayárabíàṣà, pátákó-ìdìmú ni ìbi ìpamọ̀ ìgbà díẹ̀ tí...
21
Jan
Off
Daríkiri Ọ̀rọ̀-Ìṣe (Verb) Da+orí+kiri [Daríkiri] Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gboyè daríkiri/lọ kiri ètò náà bí wọ́n ṣe ń tẹ iṣẹ́ ìwádìí wọn jáde Graduate students navigate the system as they publish research.   Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìda+orí+kiri [Ìdaríkiri] Ìdaríkiri ọkọ̀ lójú pópó Navigation of vehicle on the highway.   Ìtumọ̀ Mìíràn Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìtu+ọkọ̀ [Ìtukọ̀] Ìtukọ̀ ojú omi Water (river, ocean, sea) navigation.   Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Atu+ọkọ̀ [Atukọ̀]...
3
Jun
Off
Odù-ìdáàbòbò Noun Odù-ìdáàbòbò Odù-ìdáàbòbò ni ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ti ìdáàbòbo ìwífún nípasẹ̀ yíyí padà sí ti aláàbò. Cryptography is the science of protecting information by transforming it into a secure format. 
3
Jun
Off
Kòkòrò aṣàṣìṣe Noun Ní ọjọ́ 9 oṣù Ọ̀wẹwẹ̀, 1947 Grace rí àṣìṣe kan ní orí ẹ̀rọ Mark II tí àfòpiná kan tí ó kú sínú rẹ̀ fà. Ó yọ kòkòrò náà ó sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ìwé àkọsílẹ̀, báyìí ni a ṣe hu èdè ìperí kòkòrò aṣàṣìṣe orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá. Láti ìgbà náà lọ ni "kòkòrò aṣàṣìṣe" di èdè ìperí fún ìṣàpèjúwe àṣìṣe tàbí àléébù...
3
Jun
Off
Ìkójọpamọ́ Noun Ì + kó + jọ + pa + mọ́  Ìkójọpamọ́ ni ẹ̀dá iṣẹ́ tí a mú fi pamọ́ sí ìbòmíràn tí ó ṣe é gbà padà bí a bá pàdánù rẹ. Backup is a copy of work taken and stored elsewhere so that it may be used to restore the original after a data loss event. Verb Kó + jọ + pa + mọ́