Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá Àgbélétantẹ̀ Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ẹ̀rọ a + yára + bí + àṣá À + gbé + lé + itan + tẹ̀ Pa ojú ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àgbélétantẹ̀ yẹn dé kí o wá. Close that laptop (computer) and come.
Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá Àgbélẹ̀tẹ̀ Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Brian ni ó ṣe ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àgbélẹ̀tẹ̀ tuntun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rà. Brian made the new desktop computer that I just bought.
Ẹnu-àbáwọlé ṣiṣẹ́ Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Orí ibùdó-ìtakùn ẹnu-àbáwọlé ṣiṣẹ́ ilé ìwé wọn ni mo ti rí i. It is on their school web portal that I (saw) found it.
Odiìsanwó Noun Gbogbo ibùdó ìtakùn àgbáyé kọ́ ni ènìyàn lè mú àkóónú rẹ̀ lò ní ọ̀fẹ́, àwọn kan ń gba owó àsanlò kí òǹṣàmúlò ó tó lè rí àyè sí ohun tí wọ́n bá fẹ́. Odi ìsanwó (ògiri ìsanwó) ni ìlànà ìpààlà tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí ìdílọ́wọ́ tí kò jẹ́ kí ènìyàn rí àyè sí ìwífún orí ibùdó-ìtakùn láì ṣe pé ènìyàn san owó...
Títúmọ̀ èdè iṣẹ́ àìrídìmú Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Bí a bá ń sọ nípa èdè iṣẹ́ àìrídìmú, a kò le è yọ títúmọ̀ èdè iṣẹ́ àìrídìmú tí í ṣe aàyàn ògbufọ̀ èdè iṣẹ́ àìrídìmú kan sí èdè òmíràn. When we talk about programming language, we cannot throw aside porting which is the translation of one programming (protocol) language to another.
Àfihàn onísùnún Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Àfihàn onísùnún (oní + ìsún) Olùkọ́ wa fi àfihàn onísùnún ṣe àgbékalẹ̀ bí a ṣe ń pa aṣọ láró nípasẹ̀ lílo ìsún àwòrán mẹ́wàá. Our instructor used slide show to make a presentation of how clothes are dyed using ten picture slides.
Àjúmọ̀ṣe Ìkànnì ìkéde Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé (Adjective) Àjúmọ̀ṣe Ìkànnì ìkéde ni àwọn ohunèlò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá tí ó máa ń f'èsì sí ohunkóhun tí ònṣàmúlò bá ṣe nípasẹ̀ ìgbéjáde àwọn àkóónú ọ̀rọ̀, àwòrán tí ó ń ṣípò, àwòrándààyè, àwòrán-olóhùn, ohùn, àti àwọn ohun ìṣeré oláwòrán-olóhùn. Interactive media refers to products and services on digital computer-based systems which respond to the user's actions by presenting content such as...