Barometer
Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká Noun Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká ni ohun èlò tí a fi ń wọn ọ̀rìnrìn àyíká, tí a fi ń ṣe ìwòye ojú-ọjọ́ àti gíga. Baros tí ó túmọ̀ sí “ìwúwo” + meter "ìwọ̀n/òṣùwọ̀n" = Ẹ̀rọ òṣùwọ̀n èéfún afẹ́fẹ́ ojú-ọjọ́. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ Robert Boyle ló hu ìmọ̀ èdè-ìperí náà (1627-1691). Ọdún 1643 ni ọmọ ilẹ̀ Italy Evangelista Torricelli tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀dá-àrígbéwọ̀n hùmọ̀ ohun-èlò náà tí wọ́n kọ́kọ́...