14
Sep
Off
Asàwòrándààyè Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Asọ + àwòrán + di + ààyè A nílò asàwòrándààyè fún iṣẹ́ àkànṣe kan. We need an animator for a project. .
16
Mar
Off
Àjúmọ̀ṣe Ìkànnì ìkéde Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé (Adjective)  Àjúmọ̀ṣe Ìkànnì ìkéde ni àwọn ohunèlò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá tí ó máa ń f'èsì sí ohunkóhun tí ònṣàmúlò bá ṣe nípasẹ̀ ìgbéjáde àwọn àkóónú ọ̀rọ̀, àwòrán tí ó ń ṣípò, àwòrándààyè, àwòrán-olóhùn, ohùn, àti àwọn ohun ìṣeré oláwòrán-olóhùn. Interactive media refers to products and services on digital computer-based systems which respond to the user's actions by presenting content such as...
27
Mar
Off
Sanwósí Verb San + owó + sí Sanwósí orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká rẹ. Subscribe on your mobile phone. Fi + ọwọ́ + sí Fọwọ́sí  ìgbàròyìn tuntun Subscribe to get the latest news
22
Mar
Off
Ìdáfọ̀mọ̀ Noun Ìdá-ìfọ̀-mọ̀ Àbùdá Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ l'ó bí Ìdá-ìfọ̀-mọ̀, Ọ̀rọ̀-di-ohùn àti Ohùn-di-ọ̀rọ̀-kíkọ-sílẹ̀. Machine learning feature gave birth to Speech Recognition, Text-to-Speech and Speech-to-text.
22
Mar
Off
Pátákó-ìtẹ̀wé Noun Pátákó-ìtẹ̀wé èdè Yorùbá ni mo fi máa ń tẹ gbólóhùn lórí ẹ̀rọ. I usually type words on computer with the Yorùbá keyboard.