16
Mar
Off

Media

Ìkànnì ìkéde

Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun)

  • Ìkànnì ìkéde jẹ́ àwọn ìlànà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tàbí ìkéde. Bákan náà ni a lè lo èdè ìperí náà fún àwọn fún ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn / atẹ̀ròyìn. Bí àpẹẹrẹ, ìkànnì ìkéde ni ìwé ìròyìn, ẹ̀rọ-amóhùnmáwòràn, ẹ̀rọ-asọ̀rọ̀mágbèsì, ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Media refers to the different means of communication. Also we can use the term for news agencies / press. For example, media include newspaper, television, radio, Internet and others.

Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun)

Ìgbóhùnàtàwòránjáde

  • Ní abẹ́ ẹ̀ka ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, ìkànnì ìkéde ìgbóhùnàtàwòránjáde ni àwọn ohun àrídìmú ìgbóhùnàtàwòránjáde orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá gẹ́gẹ́ bí àká-iṣẹ́, CD ROM, flash drive, USB drive, ẹ̀rọ ayàwòrán àti àwọn ohun èlò tí a kì wọ ara ẹ̀rọ-ayárabíàṣá tí ó ní ìwífún lórí. Láfikún, ohun èlò ìgbóhùnàtàwòránjáde (àìrídìmú) tí a fi ń wo ìran tàbí gbọ́ ohùn tòun orin jẹ́ ọ̀kan lára ìkànnì ìkéde ti ìgbóhùnàtàwòránjáde.

Under the branch of computer, media refer to the hardware on the computer like hard drive, CD ROM, flash drive, USB drive and other paraphernalia with information on it attached to the computer. In addition, media players (software) that we use for viewing spectacles or listen to sound and music is also one of media.

Tags: , , , , , , , , , , ,